1 Chronicles 17:1-14

Ìlérí Ọlọ́run sí Dafidi

1 aLẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpépé (igi) ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wà lábẹ́ àgọ́.”

2Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.”

3Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé:

4“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. 5Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. 6Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’

7“Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi mú ọ kúrò ní pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ kí ó lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. 8Èmi ti wà pẹ̀lú rẹ ní, ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmí sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ tí ó wà ní ayé. 9Èmi yóò sì pèsè ààyè kan fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, kí wọn kí ó lè ní ilé tiwọn, kí a má sì ṣe dààmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀. 10Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi pẹ̀lú yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá yín.

“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín:
11Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. 12Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé. 13Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. 14Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

Copyright information for YorBMYO